Isaiah 6:8-13
8
Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?” Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”
9
Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé, “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’
10
Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì, mú kí etí wọn kí ó wúwo, kí o sì dìwọ́n ní ojú. Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran, kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀, kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn, kí wọn kí ó má ba yípadà kí a má ba mú wọn ní ara dá.”
11
Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa?” Òun sì dáhùn pé: “Títí àwọn ìlú ńlá yóò fi dahoro, láìsí olùgbé nínú rẹ̀ mọ́, títí tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ènìyàn, títí tí ilẹ̀ yóò fi dahoro pátápátá.
12
Títí tí Olúwa yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá.
13
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà, yóò sì tún pàpà padà di rírun. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹrẹbinti àti igi óákù, ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”
Settings