Isaiah 57:14-20
14
A ó sì sọ wí pé: “Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe! Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
15
Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
16
Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé, tàbí kí n máa bínú sá á, nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi èémí ènìyàn tí mo ti dá.
17
Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀; mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú; síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
18
Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn; Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
19
ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli. Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,” ni Olúwa wí, “Àti pé, Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
20
Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun tí kò le è sinmi, tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
Settings