Skip to content
Isaiah 45:18-25

Isaiah 45:18-25

18
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí, ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀, Òun wí pé: “Èmi ni Olúwa, kò sì ṣí ẹlòmíràn.
19
Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin, láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn, Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé, ‘Ẹ wá mi lórí asán.’ Èmi Olúwa sọ òtítọ́, Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.
20
“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá; ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá. Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri, tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.
21
Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá, jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀. Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́, ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe? Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa? Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi, Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà; kò sí ẹlòmíràn àfi èmi.
22
“Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là, ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé; nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.
23
Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra, ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi, ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́. Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀; nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
24
Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan ni òdodo àti agbára wà.’ ” Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí; yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn.
25
Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Israẹli ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options