Isaiah 42:14-17
14
“Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí, mo sọkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.
15
Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù, Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù n ó sì gbẹ àwọn adágún.
16
Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀, ní ipa ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ; Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná. Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí; Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
17
Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà, tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.
Settings