Isaiah 41:1-7
1
“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú mi ẹ̀yin erékùṣù! Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tún agbára wọn ṣe! Jẹ́ kí wọn wá síwájú kí wọn sọ̀rọ̀, jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́.
2
“Ta ni ó ti ru ẹnìkan sókè láti ìlà-oòrùn wá, tí ó pè é ní olódodo sí iṣẹ́ tirẹ̀? Ó gbé àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájú rẹ̀. Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀, láti kù ú ní ìyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀.
3
Ó ń lépa wọn ó sì ń kọjá ní àlàáfíà, ní ojú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí.
4
Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé, tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe? Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.”
5
Àwọn erékùṣù ti rí i wọ́n bẹ̀rù; ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì. Wọ́n súnmọ́ tòsí wọ́n sì wá síwájú;
6
èkínní ran èkejì lọ́wọ́ ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára!”
7
Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú, àti ẹni tí ó fi òòlù dán mú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú. Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.” Ó fi ìṣó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀.
Settings