Isaiah 33:18
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 18 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
15
Ẹni tí ó ń rìn lódodo tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́, tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi,
16
Òun náà yóò gbé ní ibi gíga, ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi. A ó mú oúnjẹ fún un, omi rẹ̀ yóò sì dájú.
17
Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀ yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.
18
Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá: “Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà? Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà? Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?”
19
Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́, àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin, pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni.
20
Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa, ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu, ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà; àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.
21
Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ alágbára kan fún wa. Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèké. Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn, ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.
Settings