Skip to content
Isaiah 1:21-31

Isaiah 1:21-31

21
Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè! Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí, òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n báyìí àwọn apànìyàn!
22
Fàdákà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́, ààyò wáìnì rẹ la ti bu omi là.
23
Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín, akẹgbẹ́ àwọn olè, gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri. Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.
24
Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé: “Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.
25
Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.
26
Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”
27
A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà, àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo.
28
Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó parun. Àwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.
29
“Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́ èyí tí ẹ ní inú dídùn sí, a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí tí ẹ ti yàn fúnra yín.
30
Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ ti rọ, bí ọgbà tí kò ní omi.
31
Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí ohun ìdáná, iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná, àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀, láìsí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options