Skip to content
Hosea 9:1-6

Hosea 9:1-6

1
Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli; má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín. Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà.
2
Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀.
3
Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa Efraimu yóò padà sí Ejibiti, yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.
4
Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn. Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́. Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.
5
Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?
6
Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun Ejibiti yóò kó wọn jọ, Memfisi yóò sì sin wọ́n. Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún, Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn. Ẹ̀gún yóò sì bo gbogbo àgọ́ wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options