Hosea 4:1-6
1
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. “Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́, Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà,
2
àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
3
Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù. Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú.
4
“Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá, kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà.
5
Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín. Èmi ó pa ìyá rẹ run,
6
àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀. “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀, Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
Settings