Hosea 11:1-8
1
“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.
2
Bí a ti ń pe wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn rú ẹbọ sí Baali, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.
3
Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn láradá.
4
Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn, Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.
5
“Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí. Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?
6
Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́ yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn.
7
Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ, kò ní gbé wọn ga rárá.
8
“Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu? Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Seboimu? Ọkàn mi yípadà nínú mi àánú mi sì ru sókè.
Settings