Gẹnẹsisi 50:1-7
1
Josẹfu sì ṣubú lé baba rẹ̀, ó sọkún, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu.
2
Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Israẹli baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀.
3
Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Ejibiti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.
4
Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Josẹfu wí fún àwọn ará ilé Farao pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bá mi sọ fún Farao.
5
‘Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú: sinmi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani.” Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa.’ ”
6
Farao wí pé, “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra.”
7
Báyìí ni Josẹfu gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Farao ni ó sìn ín lọ—àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà ilẹ̀ Ejibiti.
Settings