Gẹnẹsisi 32:24-30
24
Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.
25
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì.
26
Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.” Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”
27
Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.”
28
Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”
29
Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀.
30
Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”
Settings