Gẹnẹsisi 23:16-20
16
Abrahamu sì gbọ́ tí Efroni wí, Abrahamu sì wọn iye fàdákà náà fún Efroni, tí ó sọ ní etí àwọn ọmọ Hiti, irinwó (400) òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà, tí ó kọjá lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò.
17
Báyìí ni ilẹ̀ Efroni tí ó wà ni Makpela nítòsí Mamre, ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú,
18
bí ohun ìní fún Abrahamu níwájú gbogbo ará Hiti tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà.
19
Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani.
20
Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé, bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un.
Settings