Gẹnẹsisi 12:10
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 10 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
7
Olúwa sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa tí ó fi ara hàn án.
8
Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.
9
Nígbà náà ni Abramu tẹ̀síwájú sí ìhà gúúsù.
10
Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, Abramu sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí ìyàn náà mú gidigidi.
11
Bí ó ti ku díẹ̀ kí ó wọ Ejibiti, ó wí fún Sarai, aya rẹ̀ pé, “Mo mọ̀ pé arẹwà obìnrin ni ìwọ,
12
nígbà tí àwọn ará Ejibiti bá rí ọ, wọn yóò wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Wọn yóò si pa mí, ṣùgbọ́n wọn yóò dá ọ sí.
13
Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.”
Settings