Skip to content
Esra 8:9-15

Esra 8:9-15

9
nínú àwọn ọmọ Joabu: Obadiah ọmọ Jehieli àti ogún ó lé nígba ó dín méjì (218) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
10
nínú àwọn ọmọ Bani: Ṣelomiti ọmọ Josafiah, àti ọgọ́jọ ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
11
nínú àwọn ọmọ Bebai: Sekariah ọmọ Bebai àti ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú rẹ̀;
12
nínú àwọn ọmọ Asgadi: Johanani ọmọ Hakatani, àti àádọ́fà ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
13
nínú àwọn ọmọ Adonikami: àwọn ti ó gbẹ̀yìn, tì orúkọ wọn ń jẹ́ Elifaleti, Jeieli àti Ṣemaiah, àti ọgọ́ta ọkùnrin pẹ̀lú wọn;
14
nínú àwọn ọmọ Bigfai: Uttai àti Sakkuri, àti àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú wọn.
15
Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń sàn lọ sí Ahafa, a pàgọ́ síbẹ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárín àwọn ènìyàn àti àárín àwọn àlùfáà, ń kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options