Esra 8:18-20
18
Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣerebiah wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ìran Mahili, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli, àti àwọn ọmọ Ṣerebiah àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìdínlógún.
19
Àti Haṣabiah, pẹ̀lú Jeṣaiah láti ìran Merari, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ wọ́n jẹ́ ogún ọkùnrin.
20
Wọ́n sì tún mú ogún lé nígba (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili wá—àwọn ènìyàn tí Dafidi àti àwọn ìjòyè rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.
Settings