Esra 8:1-8
1
Wọ̀nyí ni àwọn olórí ìdílé àti àwọn tí ó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn tì wọn gòkè pẹ̀lú mi láti Babeli ní àkókò ìjọba Artasasta ọba:
2
nínú àwọn ọmọ Finehasi: Gerṣomu; nínú àwọn ọmọ Itamari: Daniẹli; nínú àwọn ọmọ Dafidi: Hattusi,
3
nínú àwọn ọmọ Ṣekaniah; nínú àwọn ọmọ Paroṣi: Sekariah, àti pé àádọ́jọ ọkùnrin fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ;
4
nínú àwọn ọmọ Pahati-Moabu: Elihoenai ọmọ Serahiah àti àwọn igba ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
5
nínú àwọn ọmọ Sattu: Ṣekaniah ọmọ Jahasieli àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
6
nínú àwọn ọmọ Adini: Ebedi ọmọ Jonatani, àti àádọ́ta ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
7
nínú àwọn ọmọ Elamu: Jeṣaiah ọmọ Ataliah àwọn àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
8
nínú àwọn ọmọ Ṣefatia: Sebadiah ọmọ Mikaeli, àti ọgọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
Settings