Esra 2:1-13
1
Lákòókò náà, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Juda tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrín àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Babeli (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀.
2
Àwọn wọ̀nyí bá Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu àti Baanah wá). Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Israẹli.
3
Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án (2,172)
4
Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá (372)
5
Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (775)
6
Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ àwọn ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rin lé méjìlá (2,812)
7
Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin (1,254)
8
Sattu jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún ó lé márùn-ún (945)
9
Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin (760)
10
Bani jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (642)
11
Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlélógún (623)
12
Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé méjìlélógún (1,222)
13
Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666)
Settings