Esekiẹli 44:3-16
3
Ọmọ-aládé fúnra rẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu-ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa. Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìloro ẹnu-ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.”
4
Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú mi gba ẹnu-ọ̀nà àríwá lọ sí iwájú ilé Ọlọ́run. Mo wò ó mo sì rí ògo Olúwa tí ó kún inú ilé Olúwa, mo sì dojúkọ ilẹ̀.
5
Olúwa sì sọ fún mì pé, “Ọmọ ènìyàn, wò dáradára, fetísílẹ̀ dáradára kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa òfin lórí ilé Olúwa náà. Fiyèsí ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́.
6
Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé Israẹli pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwà ìríra rẹ tí tó gẹ́ẹ́, ìwọ ilé Israẹli!
7
Ní àfikún pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà ìríra rẹ tí ó kù, ìwọ mú àwọn àjèjì aláìkọlà àyà àti ara wá sí inú ibi mímọ́ mi, ní lílo ilé mi ní ìlòkulò nígbà tí ìwọ fi oúnjẹ fún mi, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ìwọ sì ba májẹ̀mú mi jẹ́.
8
Dípò kí ìwọ pa òfin mi mọ́, ìwọ fi àwọn mìíràn sí ibi mímọ́ mi.
9
Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Àjèjì aláìkọlà àyà àti ara kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi, àti pẹ̀lú àwọn àjèjì tí ń gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli.
10
“ ‘Àwọn Lefi tí wọn rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣìnà, ti wọ́n sì ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi láti tọ àwọn ère wọn lẹ́yìn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
11
Wọn le sìn mi ní ibi mímọ́ mi, kí wọn ṣe ìtọ́jú àwọn ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run, kí wọn sì ṣe ìránṣẹ́ nínú rẹ̀; wọn le pa ẹbọ sísun, ki wọn sì rú ẹbọ fún àwọn ènìyàn, kí wọn sì dúró níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
12
Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Israẹli ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí.
13
Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti ṣe ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ nǹkan kan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ; wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn.
14
Síbẹ̀ èmi yóò mu wọn sí ìtọ́jú ilé Ọlọ́run àti gbogbo iṣẹ́ tí a gbọdọ̀ ṣe níbẹ̀.
15
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi àti àwọn ìran Sadoku tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí.
16
Àwọn nìkan ni ó gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi; àwọn nìkan ní o gbọdọ̀ súnmọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ ni iwájú mi, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mi.
Settings