Skip to content
Esekiẹli 39:21-27

Esekiẹli 39:21-27

21
“Èmi yóò ṣe àfihàn ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì rí ìyà tí mo fi jẹ wọ́n.
22
Láti ọjọ́ náà lọ, ilé Israẹli yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.
23
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Israẹli lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi. Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì ṣubú nípasẹ̀ idà.
24
Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ́ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
25
“Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Jakọbu padà kúrò ní oko ẹrú, èmi yóò ní ìyọ́nú si gbogbo ènìyàn Israẹli, èmi yóò sì ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi.
26
Wọn yóò gbàgbé ìtìjú wọn àti gbogbo àìṣòdodo tí wọ́n fihàn sí mi nígbà tí wọn ń gbé ni àìléwu ni ilẹ̀ wọn níbi tí kò ti sí ẹnikẹ́ni láti dẹ́rùbà wọ́n.
27
Nígbà tí mo ti mú wọn padà kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì kó wọn jọ pọ̀ kúrò ni ìlú àwọn ọ̀tá wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ wọn ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options