Skip to content
Esekiẹli 27:12

Esekiẹli 27:12

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 12 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
9
Àwọn àgbàgbà Gebali, àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀, wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ, gbogbo ọkọ̀ ojú Òkun àti àwọn atukọ̀ Òkun wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
10
“ ‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Puti wà nínú jagunjagun rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ. Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn ró sára ògiri rẹ, wọn fi ẹwà rẹ hàn.
11
Àwọn ènìyàn Arfadi àti Heleki wà lórí odi rẹ yíká; àti àwọn akọni Gamadi, wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ. Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ; wọn ti mú ẹwà rẹ pé.
12
“ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.
13
“ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ, wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.
14
“ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ.
15
“ ‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options