Skip to content
Esekiẹli 22:17-22

Esekiẹli 22:17-22

17
Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
18
“Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ti di ìdàrọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, idẹ, irin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà.
19
Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdàrọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jerusalẹmu.
20
Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti idẹ jọ sínú iná ìléru láti fi iná yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárín ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́.
21
Èmi yóò kó yín jọ, èmi o sì fín iná ìbínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrín rẹ̀.
22
Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò ṣe yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options