Esekiẹli 21:13-22
13
“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ń kọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’
14
“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́. Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì, kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta. Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀, tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún.
15
Kí ọkàn kí ó lè yọ́ kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀, mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun. Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná, a gbá a mú fún ìparun.
16
Ìwọ idà, jà sí ọ̀tún kí o sì jà sí òsì lọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ.
17
Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”
18
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá:
19
“Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fún idà ọba Babeli láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkóríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà.
20
La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọlu Rabba ti àwọn ará Ammoni kí òmíràn kọlu Juda, kí ó sì kọlu Jerusalẹmu ìlú olódi.
21
Nítorí ọba Babeli yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti máa lo àfọ̀ṣẹ. Yóò fi ọfà di ìbò, yóò béèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀.
22
Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jerusalẹmu yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu-ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́.
Settings