Esekiẹli 18:5-18
5
“Bí ọkùnrin olódodo kan bá wà, tó ń ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ
6
tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga, tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Israẹli, ti kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀.
7
Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipá jalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò.
8
Ẹni tí kò fi fún ni láti gba ẹ̀dá, tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ òtítọ́ láàrín ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.
9
Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo. Ó jẹ́ olódodo, yóò yè nítòótọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.
10
“Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oníwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn, tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀
11
(tí kò sì ṣe ọ̀kan nínú gbogbo iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì): “Ó ń jẹun lójúbọ lórí òkè gíga, tí ó sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́.
12
Ó ni àwọn tálákà àti aláìní lára, ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí, o gbójú sókè sí òrìṣà, ó sì ń ṣe ohun ìríra.
13
Ó ń fi owó ya ni pẹ̀lú èlé, ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù. Ǹjẹ́ irú ọkùnrin yìí wa le è yè bí? Òun kì yóò wá láààyè! Nítorí pé òun ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, kíkú ni yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀.
14
“Bí ọkùnrin yìí bá bímọ ọkùnrin, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe irú rẹ̀:
15
“Tí kò jẹun lójúbọ lórí òkè gíga tàbí kò gbójú sókè sí àwọn òrìṣà ilé Israẹli, tí kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́
16
tí kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, tí kò dá ohun ògo dúró tí kò gba èlé tàbí kò fipá jalè ṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ, tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò.
17
Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó sì ń tẹ̀lé àwọn àṣẹ mi. Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè!
18
Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
Settings