Esteri 2:1-12
1
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Ahaswerusi ọba sì dáwọ́ ìbínú un rẹ̀ dúró, ó rántí i Faṣti àti ohun tí ó ti ṣe àti àṣẹ tí ó pa nípa tirẹ̀.
2
Nígbà náà ni ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a wá ọmọbìnrin arẹwà tí kò ì ti mọ ọkùnrin rí fún ọba.
3
Àti pé kí ọba kí ó yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba láti kó gbogbo àwọn arẹwà ọmọbìnrin wọ̀nyí jọ sí ilé àwọn obìnrin ní ilé ìṣọ́ Susa. Kí a kó wọn fún ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó ṣe olùtọ́jú àwọn obìnrin; kí a ṣe ìtọ́jú u wọn dáradára.
4
Nígbà náà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Faṣti.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e.
5
Ó sì ṣe ní ìgbà náà ará a Júù kan wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mordekai ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi, ẹ̀yà Benjamini,
6
ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jekoniah ọba Juda.
7
Mordekai ní arákùnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadassa, ẹni tí ó tọ́ dàgbà nítorí tí kò ní baba bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìyá. Obìnrin yìí, ẹni tí a tún mọ̀ sí Esteri, ó dára ó sì lẹ́wà, Mordekai mú u gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nígbà tí baba àti ìyá rẹ̀ ti kú.
8
Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Susa, sí abẹ́ ìtọ́jú Hegai. A sì mú Esteri náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hegai lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin.
9
Ọmọbìnrin náà sì wù ú, ó sì rí ojúrere rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó pèsè àwọn ohun tí ó dára àti oúnjẹ pàtàkì fún un. Ó sì yan àwọn ìránṣẹ́bìnrin wúńdíá méje láti ààfin ọba òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà lọ sí ibi tí ó dára jù nínú ilé àwọn obìnrin.
10
Esteri kò tí ì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Mordekai ti pàṣẹ fún un pé kí ó má ṣe sọ ọ́.
11
Ní ojoojúmọ́ ni Mordekai máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Esteri ṣe wà ní àlàáfíà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.
12
Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ahaswerusi, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjìá fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòórùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú.
Settings