- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Ìpè sí ogun ẹ̀mí
Efesu 6:10-20
10
Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀.
11
Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù.
12
Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run.
13
Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró.
14
Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra.
15
Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìyìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà.
16
Ní àfikún, ẹ mú àpáta ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà.
17
Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
18
Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́.
19
Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí èmi lè máa fì ìgboyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìyìnrere náà.
20
Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n, kí èmi lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ.
Settings