Skip to content
Efesu 2:1-10

A gbà wá là nípa oore-ọ̀fẹ́

Efesu 2:1-10
1
Ní ti ẹ̀yin, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè, nígbà ti ẹ̀yin ti kú nítorí ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín,
2
nínú èyí tí ẹ̀yin ti gbé rí, àní bí ìlànà ti ayé yìí, gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ agbára ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí n ṣiṣẹ́ ni ìsinsin yìí nínú àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn.
3
Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ìṣẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú.
4
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa,
5
nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, oore-ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là.
6
Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kristi, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kristi Jesu.
7
Pé ni gbogbo ìgbà tí ń bọ̀ kí ó bà á lè fi ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí o pọ̀ rékọjá hàn fún wa nínú ìṣeun rẹ̀ sì wà nínú Kristi Jesu.
8
Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹ̀yin fúnra yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni,
9
kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo.
10
Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options