Deuteronomi 31:3
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 3 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
1
Nígbà náà ni Mose jáde tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí gbogbo Israẹli pé,
2
“Mo jẹ́ ọmọ ọgọ́fà ọdún báyìí àti pé èmi kò ni lè darí i yín mọ́. Olúwa ti sọ fún mi pé, ‘Ìwọ kò ní kọjá Jordani.’
3
Olúwa Ọlọ́run rẹ fúnra rẹ̀ ni yóò rékọjá fún ọ. Yóò pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run níwájú rẹ, ìwọ yóò sì mú ìní ilẹ̀ wọn, Joṣua náà yóò rékọjá fún ọ, bí Olúwa ti sọ.
4
Olúwa yóò sì ṣe fún wọn ohun tí ó ti ṣe sí Sihoni àti sí Ogu ọba Amori, tí ó parun pẹ̀lú ilẹ̀ ẹ wọn.
5
Olúwa yóò fi wọ́n fún ọ, kí o sì ṣe sí wọn gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún ọ.
6
Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ, Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”
Settings