Skip to content
Daniẹli 8:3-14

Daniẹli 8:3-14

3
Mo wo òkè mo sì rí àgbò kan tí ó ní ìwo méjì níwájú mi, ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, àwọn ìwo náà sì gùn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan gùn ju èkejì lọ, èyí tí ó gùn jù ni ó yọ jáde kẹ́yìn.
4
Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, sí àríwá, àti sí gúúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó le è dojúkọ ọ́, kò sí ẹnìkan tí ó le è yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.
5
Bí mo ṣe ń ronú nípa èyí, lójijì ni òbúkọ kan tí ó ní ìwo láàrín ojú u rẹ̀ méjèèjì jáde láti ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó la gbogbo ayé kọjá láìfi ara kan ilẹ̀.
6
Ó tọ àgbò tí ó ni ìwo méjì náà wá, èyí tí mo rí tó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, ó sì dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìrunú tí ó lágbára.
7
Mo rí i tí ó fi ìtara kọlu àgbò náà, ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì. Àgbò náà kò sì ní agbára láti dojúkọ ọ́, Òbúkọ náà kàn án mọ́lẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì ṣí ẹni tí ó lè gba àgbò náà là kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.
8
Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.
9
Lára ọ̀kan nínú wọn, ìwo mìíràn yọ jáde, ó kékeré, ṣùgbọ́n ó dàgbà nínú agbára sí ìhà gúúsù, àti sí ìhà ìlà-oòrùn àti sí ilẹ̀ dídára.
10
Ó sì dàgbà títí ó fi kan ẹgbẹ́ ogun ọ̀run, ó sì jù lára àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run sí ayé ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀,
11
ó sì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọmọ-aládé ẹgbẹ́ ogun ọ̀run; ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ààyè ibi mímọ́ rẹ̀.
12
A fún un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojoojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀, ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe.
13
Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún un pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúṣẹ—ìran nípa ẹbọ ojoojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó mú ìsọdahoro wa, àní láti fi ibi mímọ́ àti ogun ọ̀run fún ni ní ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”
14
Ó sọ fún mi pé, “Yóò gbà tó ẹgbọ̀kànlá lé lọ́gọ́rùn-ún (2,300) alẹ́ àti òwúrọ̀; lẹ́yìn náà ni a ó tún ibi mímọ́ yà sí mímọ́.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options