Amosi 1:10
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 10 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
7
Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run.
8
Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò, ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú. Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
9
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tire àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún Edomu. Wọn kò sì náání májẹ̀mú ọbàkan,
10
Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire, tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”
11
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Edomu, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀, Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù, ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí, ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́,
12
Èmi yóò rán iná sí orí Temani, tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.”
13
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ammoni, àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gileadi kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.
Settings