Skip to content
Ìṣe àwọn Aposteli 6:1-7

Ìṣe àwọn Aposteli 6:1-7

1
Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú wà ní àárín àwọn Helleni tí ṣe Júù àti àwọn Heberu tí ṣe Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín fún ni ojoojúmọ́.
2
Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì.
3
Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí.
4
Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”
5
Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Stefanu, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti Filipi, àti Prokoru, àti Nikanoru, àti Timoni, àti Parimena, àti Nikolasi aláwọ̀ṣe Júù ará Antioku.
6
Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Aposteli; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.
7
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerusalẹmu, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options