Ìṣe àwọn Aposteli 22:1-5
1
“Ẹ̀yin ará àti baba, ẹ gbọ́ tí ẹnu mi nísinsin yìí.”
2
Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ni èdè Aramaiki, wọ́n túbọ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nígbà náà ni ó wí pé,
3
“Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tarsu ìlú kan ní Kilikia, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gamalieli ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì ní ìtara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní.
4
Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin tobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú,
5
àní bí olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo àjọ àwọn alàgbà tí lè jẹ́ mi ní ẹ̀rí. Mo tilẹ̀ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Damasku láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní dídè wá sí Jerusalẹmu, láti jẹ wọ́n ní yà.
Settings