Skip to content
Ìṣe àwọn Aposteli 18:18-23

Ìṣe àwọn Aposteli 18:18-23

18
Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea, nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́.
19
Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Efesu, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀.
20
Nígbà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó bá àwọn jókòó díẹ̀ sí i, ó kọ̀.
21
Ṣùgbọ́n ó dágbére fún wọn, ó sì wí pé, “Èmi ó tún padà tọ̀ yín wá, bí Ọlọ́run bá fẹ́.” Ó sì lọ kúrò láti Efesu.
22
Nígbà tí ó sì tí gúnlẹ̀ ni Kesarea, ó gòkè lọ si Jerusalẹmu láti kí ìjọ, lẹ́yìn náà ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Antioku.
23
Nígbà tí ó sì gbé ọjọ́ díẹ̀ níbẹ̀, ó n lọ, láti káàkiri ni agbègbè Galatia àti Frigia, o ń mu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options