Skip to content
2 Timotiu 3:1-9

2 Timotiu 3:1-9

1
Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀ pé, ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé.
2
Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́.
3
Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere,
4
oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ.
5
Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.
6
Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri.
7
Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́.
8
Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́.
9
Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options