Skip to content
2 Samuẹli 8:3-8

2 Samuẹli 8:3-8

3
Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọmọ Rehobu, ọba Soba, bí òun sì ti ń lọ láti mú agbára rẹ̀ bọ̀ sípò ni odò Eufurate.
4
Dafidi sì gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ẹlẹ́ṣin, àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Dafidi sì já gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́ wọn ní pàtì, ṣùgbọ́n ó dá ọgọ́rùn-ún kẹ̀kẹ́ sí nínú wọn.
5
Nígbà tí àwọn ará Siria ti Damasku sì wá láti ran Hadadeseri ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ènìyàn nínú àwọn ará Siria.
6
Dafidi sì fi àwọn ológun sí Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì wá sin Dafidi, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá, Olúwa sì pa Dafidi mọ́ níbikíbi tí o ń lọ.
7
Dafidi sì gba àṣà wúrà tí ó wà lára àwọn ìránṣẹ́ Hadadeseri, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu.
8
Láti Beta, àti láti Berotai, àwọn ìlú Hadadeseri, ọba Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ wá.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options