Skip to content
2 Peteru 1:5-11

2 Peteru 1:5-11

5
Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere;
6
àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù.
7
Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì.
8
Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi.
9
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.
10
Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú, nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú.
11
Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options