2 Ọba 9:21-28
21
“Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Joramu pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Joramu ọba Israẹli àti Ahasiah ọba Juda, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jehu. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli.
22
Nígbà tí Joramu rí Jehu, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jehu?” “Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jehu dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti màmá rẹ Jesebeli di púpọ̀?”
23
Joramu yí ọwọ́ rẹ̀ padà, ó sì sálọ, ó sì ń pe Ahasiah, “Ọ̀tẹ̀ dé, Ahasiah!”
24
Nígbà náà, Jehu fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Joramu láàrín èjìká méjèèjì. Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀.
25
Jehu sọ fún Bidikari, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí oko tí ó jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. Rántí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Ahabu baba à rẹ nígbà tí Olúwa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀,
26
‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Naboti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa.”
27
Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀.
28
Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi.
Settings