Skip to content
2 Ọba 9:11-20

2 Ọba 9:11-20

11
Nígbà tí Jehu jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?” Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jehu fèsì.
12
“Ìyẹn kì í ṣe òótọ́!” Wọ́n wí. “Sọ fún wa.” Jehu wí, “Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.” ’ ”
13
Wọ́n ṣe gírí, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní orí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ìpè, wọ́n sì kígbe, “Jehu jẹ ọba!”
14
Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ sí Joramu. (Nísinsin yìí Joramu àti gbogbo Israẹli ti ń dáàbò bo Ramoti Gileadi nítorí Hasaeli ọba Aramu.
15
ṣùgbọ́n ọba Joramu ti padà sí Jesreeli láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Aramu ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hasaeli ti Aramu.) Jehu wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jesreeli.”
16
Nígbà náà Jehu wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jesreeli, nítorí Joramu ń sinmi níbẹ̀ àti Ahasiah ọba Juda sì sọ̀kalẹ̀ láti wá wò Joramu.
17
Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jesreeli, rí ọ̀wọ́ ogun Jehu tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.” “Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Joramu pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”
18
Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jehu ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ” “Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu sì dáhùn. “Bọ́ sí ẹ̀yìn mi.” Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “Ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.”
19
Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì. Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ: “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu dáhùn, “Dúró sí ẹ̀yìn mi.”
20
Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jehu ọmọ Nimṣi, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options