2 Ọba 23:30-33
30
Ìránṣẹ́ Josiah gbé ara rẹ̀ wá nínú kẹ̀kẹ́ láti Megido sí Jerusalẹmu ó sì sin ín sínú isà òkú rẹ̀. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah. Ó fi àmì òróró yàn án, ó sì ṣe é ní ọba ní ipò baba a rẹ̀.
31
Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó wá láti Libina.
32
Ó ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.
33
Farao Neko sì fi sí inú ìdè ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má ba à lè jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Ó sì tan Juda jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì wúrà kan.
Settings