Skip to content
2 Ọba 23:24-28

2 Ọba 23:24-28

24
Síwájú sí, Josiah sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Juda àti ní Jerusalẹmu. Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hilkiah àlùfáà ti rí nínú ilé Olúwa.
25
Kò sì sí ọba kankan níwájú tàbí lẹ́yìn Josiah tí ó dàbí rẹ̀, tí ó yí padà sí olúwa tinútinú àti gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí i rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Mose.
26
Bí ó ti wù kí ó rí Olúwa kò yípadà kúrò nínú ìmúná ìbínú ńlá rẹ̀ tí ó jó sí Juda, nítorí gbogbo èyí tí Manase ti ṣe láti mú un bínú.
27
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí pé, “Èmi yóò mú Juda kúrò pẹ̀lú níwájú mi, bí mo ti mú Israẹli, èmi yóò sì kó Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí mo yàn àti ilé Olúwa yìí, nípa èyí tí mo sọ, ‘Níbẹ̀ ni orúkọ mi yóò wà?’ ”
28
Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Josiah, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options