跳到主要内容
2 Ọba 19:20-28

2 Ọba 19:20-28

20
Nígbà náà Isaiah ọmọ Amosi rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Sennakeribu ọba Asiria.
21
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀, “ ‘Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni kẹ́gàn rẹ ó sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà. Ọmọbìnrin Jerusalẹmu mi orí sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti sálọ.
22
Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀? Lórí ta ni ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga? Lórí ẹni mímọ́ ti Israẹli!
23
Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa. Tì wọ sì wí pé, “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá, sí ibi gíga jùlọ Lebanoni. Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, àti ààyò igi firi rẹ̀. Èmi a sì lọ sí orí òkè ìbùwọ̀ rẹ̀ sínú ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ̀.
24
Mo ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì, mo sì mu omi níbẹ̀. Pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi, èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Ejibiti.”
25
“ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́? Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án. Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀; nísinsin yìí mo ti mú wá sí ìkọjá pé ìwọ ti yí ìlú olódi padà dí òkìtì àlàpà òkúta.
26
Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa, wọ́n ti dà á láàmú wọ́n sì ti ṣọ́ di ìtìjú. Wọ́n dàbí koríko igbó lórí pápá, gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbàsókè, gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde.
27
“ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọ dúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbí lọ àti bí ìwọ ṣe ìkáàánú rẹ: sí mi.
28
Ṣùgbọ́n ìkáàánú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi, Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imú rẹ àti ìjánu mi sí ẹnu rẹ, èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ.’
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options