2 Ọba 10:1-6
1
Nísinsin yìí, Ahabu ṣì ní àádọ́rin ọmọkùnrin ní ìdílé rẹ̀ ní Samaria. Bẹ́ẹ̀ ni, Jehu kọ lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samaria: sí àwọn oníṣẹ́ Jesreeli, sí àwọn àgbàgbà àti sí àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu. Ó wí pé,
2
“Ní kété tí lẹ́tà bá ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ ọ̀gá rẹ wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹṣin, ìlú olódi kan pẹ̀lú ohun ìjà,
3
yan èyí tí ó dára àti èyí tí ó níye jùlọ nínú àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ, kí o sì gbé e lé orí ìtẹ́ baba a rẹ̀. Nígbà náà, kí o sì jà fún ilé ọ̀gá à rẹ.”
4
Ṣùgbọ́n ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wí pé, “Tí ọba méjì kò bá le kojú ìjà sí i, báwo ni a ṣẹ le è ṣe é?”
5
Bẹ́ẹ̀ ẹni tí ń ṣe olórí ilé, ẹni tí ń ṣe olórí ìlú ńlá, àwọn àgbàgbà àti àwọn olùtọ́jú náà rán iṣẹ́ yìí sí Jehu, pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́ pẹ̀lú, àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Àwa kì yóò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ọba; ìwọ ṣe ohunkóhun tí o rò pé ó dára jù lójú rẹ.”
6
Nígbà náà ni Jehu kọ lẹ́tà kejì sí wọn, wí pé, “Tí ìwọ bá wà ní ìhà tèmi, tí o sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, mú orí àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jesreeli ní ìwòyí ọ̀la.” Nísinsin yìí, àwọn ọmọ-aládé àádọ́rin ọkùnrin, ń bẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ńlá ìlú náà tí ń tọ́ wọn.
Settings