Skip to content
2 Ọba 10:1-11

2 Ọba 10:1-11

1
Nísinsin yìí, Ahabu ṣì ní àádọ́rin ọmọkùnrin ní ìdílé rẹ̀ ní Samaria. Bẹ́ẹ̀ ni, Jehu kọ lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samaria: sí àwọn oníṣẹ́ Jesreeli, sí àwọn àgbàgbà àti sí àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu. Ó wí pé,
2
“Ní kété tí lẹ́tà bá ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ ọ̀gá rẹ wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹṣin, ìlú olódi kan pẹ̀lú ohun ìjà,
3
yan èyí tí ó dára àti èyí tí ó níye jùlọ nínú àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ, kí o sì gbé e lé orí ìtẹ́ baba a rẹ̀. Nígbà náà, kí o sì jà fún ilé ọ̀gá à rẹ.”
4
Ṣùgbọ́n ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wí pé, “Tí ọba méjì kò bá le kojú ìjà sí i, báwo ni a ṣẹ le è ṣe é?”
5
Bẹ́ẹ̀ ẹni tí ń ṣe olórí ilé, ẹni tí ń ṣe olórí ìlú ńlá, àwọn àgbàgbà àti àwọn olùtọ́jú náà rán iṣẹ́ yìí sí Jehu, pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́ pẹ̀lú, àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Àwa kì yóò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ọba; ìwọ ṣe ohunkóhun tí o rò pé ó dára jù lójú rẹ.”
6
Nígbà náà ni Jehu kọ lẹ́tà kejì sí wọn, wí pé, “Tí ìwọ bá wà ní ìhà tèmi, tí o sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, mú orí àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jesreeli ní ìwòyí ọ̀la.” Nísinsin yìí, àwọn ọmọ-aládé àádọ́rin ọkùnrin, ń bẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ńlá ìlú náà tí ń tọ́ wọn.
7
Nígbà tí ìwé náà dé ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú gbogbo àwọn ọmọ ọba tí gbogbo wọ́n jẹ́ àádọ́rin wọ́n sì pa gbogbo wọn. Wọ́n gbé orí wọn sí inú apẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ránṣẹ́ sí Jehu ní Jesreeli.
8
Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé, ó sọ fún Jehu, “Wọ́n ti gbé orí àwọn ọmọ ọba náà wá.” Nígbà náà Jehu pàṣẹ, “Ẹ tò wọ́n ní òkìtì méjì ní àtiwọ ẹnu ibodè ìlú ńlá títí di òwúrọ̀.”
9
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jehu jáde lọ. Ó dúró níwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin jẹ́ aláìjẹ̀bi. Èmi ni mo dìtẹ̀ sí ọ̀gá mi, tí mo sì pa á, ṣùgbọ́n ta ni ó pa gbogbo àwọn wọ̀nyí?
10
Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Ahabu tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah.”
11
Bẹ́ẹ̀ ni Jehu pa gbogbo ẹni tí ó kù Jesreeli ní ilé Ahabu, pẹ̀lúpẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options