Skip to content
2 Kronika 6:22-31

2 Kronika 6:22-31

22
“Nígbà tí ọkùnrin kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì mú búra, tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí,
23
nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn. Ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe. Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀.
24
“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé Olúwa yìí,
25
nígbà náà, ni kí o gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Israẹli jì wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn baba wọn.
26
“Nígbà tí a bá ti ọ̀run, tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú,
27
nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó máa rìn, kí o sì rọ òjò sórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní.
28
“Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọ́njú tàbí ààrùn lè wá.
29
Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Israẹli olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé Olúwa yìí.
30
Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run ibùgbé rẹ dáríjì, kí o sì pín fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí i gbogbo ohun tí ó ṣe, nígbà tí ìwọ ti mọ ọkàn rẹ̀ (nítorí ìwọ nìkan ni ó mọ ọkàn ènìyàn.)
31
Bẹ́ẹ̀ ni kí wọn kí ó lè bẹ̀rù rẹ kí wọn kí ó sì rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń gbé nínú ilé tí o ti fi fún àwọn baba wa.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options