2 Kronika 16:7-12
7
Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.
8
Àwa kì í ṣe ará Etiopia àti àwọn ará Libia àwọn alágbára ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ.
9
Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”
10
Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.
11
Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli.
12
Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan.
Settings