1 Samuẹli 4:6-9
6
Ní ìgbà tí àwọn Filistini gbọ́ ariwo náà wọ́n béèrè pé, “Kí ni gbogbo ariwo yìí ní ibùdó Heberu?” Nígbà tí wọ́n mọ̀ wí pé àpótí ẹ̀rí Olúwa ti wá sí ibùdó,
7
àwọn Filistini sì bẹ̀rù pé, Ọlọ́run kékeré ti wọ ibùdó, wọ́n wí pé, “A wọ wàhálà, irú èyí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí.
8
Àwa gbé! Ta ni yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ Ọlọ́run alágbára yìí? Àwọn ni Ọlọ́run tí ó fi ìpọ́njú pa àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo àjàkálẹ̀-ààrùn ní aginjù.
9
Ẹ jẹ́ alágbára Filistini, ẹ ṣe bí ọkùnrin, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin yóò di ẹrú àwọn Heberu, bí wọ́n ti jẹ́ sí i yín. Ẹ jẹ́ alágbára ọkùnrin, kí ẹ sì jagun!”
Settings