Skip to content
1 Ọba 8:1-7

1 Ọba 8:1-7

1
Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli àti gbogbo àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Israẹli jọ papọ̀, níwájú Solomoni ọba ní Jerusalẹmu, láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá láti ìlú Dafidi, tí ń ṣe Sioni.
2
Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì pe ara wọn jọ sọ́dọ̀ Solomoni ọba ní àkókò àjọ ọdún ní oṣù Etanimu tí í ṣe oṣù keje.
3
Nígbà tí gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli dé, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí,
4
wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àgọ́ àjọ ènìyàn àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi sì gbé wọn gòkè wá,
5
àti Solomoni ọba, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùntàn àti màlúù tí a kò le mọ iye, àti tí a kò le kà rú ẹbọ.
6
Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, Ibi Mímọ́ Jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù.
7
Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options