1 Ọba 10:23-27
23
Solomoni ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ.
24
Gbogbo ayé sì ń wá ojú Solomoni láti gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sí i ní ọkàn.
25
Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún olúkúlùkù àwọn tí ń wá sì ń mú ẹ̀bùn tirẹ̀ wá, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò wúrà àti ẹ̀wù, àti tùràrí olóòórùn dídùn, ẹṣin àti ìbáaka.
26
Solomoni sì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ; ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó fi pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú ọba ní Jerusalẹmu.
27
Ọba sì jẹ́ kí fàdákà pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti igi kedari ni ó ṣe kí ó dàbí igi sikamore tí ń bẹ ní àfonífojì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Settings