1 Kọrinti 9:1-14
1
Èmi kò ha ni òmìnira bí? Èmi kò ha ń ṣe aposteli bí? Èmi kò ha ti rí Jesu Olúwa bí? Ẹ̀yìn ha kọ́ ní èrè iṣẹ́ mi nínú Olúwa bí?
2
Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe aposteli. Dájúdájú aposteli ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ aposteli mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa.
3
Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ aposteli mi.
4
Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí?
5
Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa.
6
Ṣé èmi nìkan àti Barnaba, àwa kò ha ní agbára láti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa ni?
7
Ta ni ó ṣíṣẹ́ ológun tí ó sanwó ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀? Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́ ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́ ẹran?
8
Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì?
9
Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mose, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi?
10
Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè.
11
Bí àwa ti fún irúgbìn ohun ti ẹ̀mí sínú ọkàn yín, ohun ńlá ha ni bí àwa ó ba ká ohun ti yín tí ṣe ti ara?
12
Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù? Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má ba à ṣe ìdènà fún ìyìnrere Kristi.
13
Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, láti fi ṣe ìtọ́jú ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa ṣe àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ.
14
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù ìyìnrere kí wọn sì máa jẹ́ nípa ìyìnrere.
Settings