1 Kronika 7:20-26
20
Àwọn ìran ọmọ Efraimu: Ṣutelahi, Beredi ọmọkùnrin rẹ̀, Tahati ọmọ rẹ̀, Eleadah ọmọ rẹ̀. Tahati ọmọ rẹ̀
21
Sabadi ọmọ, rẹ̀, àti Ṣutelahi ọmọ rẹ̀. Eseri àti Eleadi ni a pa nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gati nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn
22
Efraimu baba wọn ṣọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ wá láti tù ú nínú.
23
Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Beriah nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà.
24
Ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Ṣerah, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Beti-Horoni àti Useni-Ṣerah pẹ̀lú.
25
Refa jẹ́ ọmọ rẹ̀, Resefi ọmọ rẹ̀, Tela ọmọ rẹ̀, Tahani ọmọ rẹ̀,
26
Laadani ọmọ rẹ̀ Ammihudu ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀,
Settings